ÀWỌN ÌTÀN ÀLỌ ́, ÌTÀN ÌWÁSẸ ̀, ORÚKỌ ÀWỌN AKỌNI ILẸ ỲORÙBÁ, ORIN ÀTI AWỌN EWÌ KÉÉKÈÈKÉ Adésànyà, A. O., Ojo E. T. & Olómù, Oyèwọlé O. Department of Linguistics, African languages and Communication Arts 4.0 Ifáàrà Ọ̀kan pàtàkì lára ewì alohùn Yorùbá tí ó gbajúmọ̀ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìdáni lárayá ni Àlọ́ jẹ́ a lè sọ pé àwọn ìtàn àlọ́ jẹmọ́ ìgbé ayé àwọn Yorùbá nítorí pé ó jẹ mọ́ ìdánilẹḱọ̀ọ́ fún ọmọdé àti àgbàlagbà pẹ̀ lú àyíká wọn, àgbékalẹ̀ rẹ̀ tún jẹmọ́ èrò láti mú kí ọmọdé lè ronú ìgbà ayé wọn, ìtàn ìwásẹ̀ ẹ̀wẹ̀ ni àwọn ìtàn àràbájọ tí a ń lò láti sọ ìdí abájọ àwọn nǹkan tí a ní òye pé Ọlọ́run da ṣùgbọ́n tí iṣẹ̀dá wọn farasíni nítorí pé wọ́n níwà lójú ṣùgbọ́n tí a ní ìgbàgbọ́ nínú wọn, ìtàn ìwásẹ̀ fẹ́fara pẹ́ àlọ́ nítorí pé àwọn méjéèjì fẹ́rẹẹ̀́ ní àbùdá kan náà nínú èrò, àgbékalẹ̀ àti ìhun wọn. Yorùbá bọ̀ wọ́n ní tí a bá perí akọni, àá fidà lalẹ̀ gàààràgà! Ẹnìkan kìí jẹ ́àwádé, ọ̀pọ̀ èèyàn níí jẹ ́ àwùjọ. Bí èèyàn ṣe wá pọ̀ tó ní àwùjọ, àwọn ẹ̀dá kan wà tí wọ́n jẹ́ àkàndá tí wọ́n ya ara wọn sọ́ tọ̀ nípa iṣẹ ́ ìrìjú wọn. Akitiyan àwọn àkàndá ẹ̀dá wọ̀nyí àti ipa tí wọ́n kó ní àwùjọ ló sọ wọ́n di olú tàbí akọ-ẹni tí wọ́n ń pè ní akọni láàrín àwọn ènìyàn wọn. Yorùbá bọ, wọ́n ní ọkùnrin tí ó ń sun rárà fún ọkùnrin ẹgbẹ́ẹ̀ , akọ iṣẹ ́ ló ń ṣe, àwọn wọ̀nyí jà fita- fita wọn fi ẹ̀mí ara wọn lélẹ̀ , wọ́n tayọ, wọ́n mókè, wọ́n gbóúnjẹ fẹǵbẹ̀ , wọ́n sì gba àwo bọ̀ , èyí ni ó sọ wọ́n di akọni láwùjọ. Nínú iṣẹ ́yìí, a ó wo Àlọ́ , ìtàn ìwásẹ̀ àti àwọn akọni ilẹ̀ Yorùbá gẹ́ge bí ọ̀nà pàtàkì fún ìdánilárayá. Ìtàn jẹ́ pípè sí àkíyèsí àyíká ẹni, kíkọ́mọlọ́gbọ́n àti òye fún ìgbé ayé tí ó rọrùn, ìgbádùn bẹ́ẹ̀ ni ó tún wà fún ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ó tayọ. Ọ̀nà mẹ ́ ta pàtàkì ni a fẹ́ gbà ṣe atótónu lórí orí ọ̀rọ̀ tí a yàn láàyò, ìyẹni àlọ́ onítàn àti àlọ́ àpamọ̀ , ìtàn ìwásẹ̀ àti ìtàn àwọn akọni. Falókun àti Oyèríndè (2014:1) sọ pé èdè tí ó rẹwà, tí ó dùn tí ó sì gún régé létí ni a fi ń gbé àlọ́ àpamọ̀ àti àpagbè kalẹ̀ bákan náà ni kìn lẹ́yìn nígbà tí wọ́n sọ pé “àlọ́ ni akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ apamọ́ lẹ̀rín, akọ́mọlédè àti akọmọ́ láṣà”. Àkàngbé (2016:368) náà sọ nípa pàtàkì àlọ́ pé... “àtàrí àjànàkú ni èdè rẹ̀ , ... Ìhun rẹ falàkì, àsúnkì ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ ni tí ó ń ṣe àfihàn èrò Yorùbá nípa àyíká wọn. Ó ṣe pàtàkì láti sọ pé àgbà àti ọmọdé ni ó máa ń pa àlọ́ , sọ ìtàn ìwásẹ̀ àti ìtàn àwọn akọni ní ilẹ̀ Yorùbá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọdé ni osúnsún afọ̀ àlọ́ , nítorí wọ́n ní àwọn àgbà ṣe máa ń ṣe àgbékalẹ̀ àlọ̀ láti fi ṣe ìdánwò fún wọn pé èrò pé kí wọ́n ó lè tẹ̀ lé ìrònú jinlẹ̀ wá ojútùú sí ìṣòro tàbí ìdojúkọ yòówù tí wọ́n leè fẹ́ bá pàdé nínú ìrìn àjò wọn láyé. Yoruba GNS Page 27 of 199 Bí a ti rí àpẹẹrẹ ìtàn àlọ́ , ìtàn ìwásẹ̀ àti ìtàn akọni tí àwọn ọmọdé lè dá pa fún ara wọn bẹẹ̀́ náà ni a rí àwọn èyí tí ó pé fún kí wọ́n bèèrè ìtumọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn àgbà tí wọ́n bá pa irú àlọ́ tí ìtumọ̀ rẹ̀ rú wọn lójú. Èyí jẹmọ́ ọ̀rọ̀ Adélékè (1999:107) tí ó sọ bí ìwúlò lítíréṣọ̀ ṣe di ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìdánilárayá nǹkan le ó wí pé: The purpose or arts, apparts from these two overriding goals, is to inform, organize, influence, intigate, matter and stir the member of the audience (that is a representation of the whole community in to action) Lááríjà iṣẹ́ ọnà, yàtọ̀ fún iṣẹ́méjì pàtàkì tí ó borí àwọn yòókù, ó ṣiṣẹ ́ ìfitónilétí, ṣe àkójọpọ̀ , nípa ríru nǹkan sókè láti bẹ̀rẹ̀ , ṣíṣe ètò ìwúrí àti láti mú kí àwọn ènìyàn àwùjọ parapọ̀ nínú iṣẹ ́kan. Àlàyé wọ̀nyí wà ní ìbámu pẹ̀ lú èrò Fáfunwá (1974:20) nígbà tí ó sọ èròńgbà ẹ̀kọ́ ìbílẹ̀ Áfríkà, ó jẹ ́ kí ó di mímọ̀ pé èrèdí ẹ̀kọ́ yìí ni láti jẹ́ kí ẹnikọ̀ọ̀kan jẹ́ olóòtọ́ , ẹni tí a lè bọ̀wọ̀ fún, ẹni tí ó kún ojú òsùnwọ̀n aláfọwọ́sowọ́ pọ̀ àti ẹni tí yóò máa ṣe gbogbo nǹkan rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀ lú àlàkalẹ̀ ètò àwùjọ. Kókó ohun tí à ń gbìyànjú àti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nipé kí ọmọ leè dá dúró ni ayé ró ní ipò yòówù tí ó bá ti bá ara rẹ̀ ni pé wíwọ àwòkọ́ṣe ọgbọ́n òye àti ẹ̀kọ́ tí ó rí kọ́ nípasẹ̀ àlọ́ , ìtàn ìwásẹ̀ àti ìtàn àwọn akọni tí ó ti lọ. 4.1 Àlọ́ (Folktales) Alẹ́ lẹ́yìn iṣẹ́ òòjọ́ tí ọwọ́ bá dilẹ̀ ni Yorùbá máa ń pa àlọ́ . Àgbàlagbà kan lè pa àloọ́ fún ọmọdé, ọmọdé èyí tí ó bá sì ti bá àgbà rìn lè jẹ́ apàlọ́ tí àwọn yòókù yóò sì jẹ ́àgbálọ̀ọ́ . Ọlátúnjí (1984) ṣàlàyé bí àwọn Yorùbá ṣe máa ń sọ pé “afọ́ jú ni ó máa ń pa àlọ́ ọ̀sán” àlàyé onímọ̀ náà wà ní ìbámu tí Ògúndèjì (1991) pè kí ó má baà jẹ ́ ìpalára fún iṣẹ ́òòjọ́ wọn ni wọ́n ṣe máa ń wí bẹ́ẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí Yorùbá máa ń korò ojú sí ìmẹ ́ lẹ́ṣíṣe wọn kìí jẹ́ kí erè ṣíṣe di iṣẹ́ ni àlọ́ pípa àti àwọn ìtàn akọ́nilọ́gbọ́n mìíràn máa ń wáyé. Nǹkan kejì tí ó ṣe gbòógì ni, àlọ́ ni ibùdó tàbí ibi ìṣeré. Èyí lè jẹ́ gbàgede tàbí ní iwájú ìtà agboolé, ó sì sáábà máa ń jẹ ́àsìkò tí wọ́n gbé oúnjẹ alẹ́ kanọ́ , kí àwọn ọmọdé má baà sùn láìjẹun, wọn yóò máa ṣe ètò tàbí àgbékalẹ̀ àlọ́ tí ó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá tí wọ́n fi máa ń gbé àlọ́ kalẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ . Kìí sí àkànlò èdè tàbí ọ̀rọ̀ àyálò bí ó ti wù kí ó mọ nínú pípè èdè àlọ́ . Abala méjì ọ̀ tọ̀ọ̀ tọ̀ ni a pín àlọ́ sí láàrín àwọn ọmọ káàrọ́-oò-jíire, èkínní ni àlọ́ àpagbè tàbí àlọ olórin, èkejì ni àlọ́ àpamọ̀ tí ó máa ń jẹ ́ ibéèrè àti ìdáhùn. 4. 2 Àlọ́ Àpamọ̀ Àlọ́ àpamọ̀ jẹ́ eré ọpọlọ àti ọ̀nà láti mú kí ọmọdé ní àròjinlẹ̀ . Ọmọ tí kò bá ní ìfarabalẹ̀ , òye àti àròjinlẹ̀ kò lè mọ ìtumọ̀ àloọ àpamọ̀ . Àlọ́ àpamọ̀ kìí ní orin bẹẹ̀́ ni a kìí sọ ìtàn nínú rẹ̀ . Bí a bá sọ pé, Àkùkọ baba mi kan láéláé Yoruba GNS Page 28 of 199 Àkùkọ baba mi kan làèlàè Owó ní í jẹ kìí jẹ àgbàdo Kí ni o? Nínú àlọ́ àpamọ̀ , àwòrán ni a máa ń fi ọ̀rọ̀ yá, bẹ́ẹ̀ni a máa ń gbé àbùdá ènìyàn wọ ohun tí kìí ṣe ènìyàn gẹ́gẹ́ bí a ṣe ríi ní àpẹẹrẹ òkè yìí. Àkùkọ tí a fi dí pò ènìyàn pé owó níí jẹ kìí jẹ àgbàdo nínú àlọ́ yìí. Kóòtù adájọ́ ni ìtumọ̀o àlọ yìí nítorí pé wá lónìí, wá lọ́ la ẹjọ́ kóòtù owó níná ni yóò padà já sí. Àpẹẹrẹ àwọn àlọ́ àpamọ̀ mìíràn: i. Òrúkú tindí tindí, òrúkú tindì tindì, orúkú bí igba ọmọ, ó lé gbogbo wọn ní tìróò. Kí ni o? ii. Òrúkú tindí tindí, òrúkú tindì tindì, orúkú ní igba ọmọ, gbogbo wọn ya àjẹ́Kí ni o? iii. Ọ̀pá tínrín kanlẹ̀ ó kan ọ̀run. Kí ni o? iv. Awẹ́ obì kan à jẹ d’Ọ́yọ̀ọ́ . Kí ni o? v. Wọ́n ní kí ó wá yá iná, o yá iná wọ́n ní kí o wá ya oòrùn, o yá oòrùn, wọ́n, ní kí ó wá wẹ̀ , o ní ikú dé. Kí ni o? 4.3 Ìwúlò Àlọ̀Àpamọ̀ • Àlọ́ àpamọ̀ ń mú kí ọmọdé ronú jinlẹ̀ • Ó ń jẹ́ kí ọpọlọ àwọn èwe jí pépé Yàtọ̀ sí àlọ́ àpamọ̀ , àlọ́ onítàn àpagbè tàbí àlọ́ olórin ni Yorùbá tún máa ń lò láti kọ́ ọmọdé lẹḱọ̀ọ́ nípa ìrírí ayé, ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní agbègbè wọn àti wíwá ojútùú sí ìṣòro tí wọ́n bá lè dojúkọ nínú ìrìn àjò ìgbòkè gbodò ilé ayé wọn. • Ó ń jẹ́ kí ọmọdé ní ìgboyà láti dáhùn ìbéèrè • Ó ń jẹ́ kí àwọn ọmọdé ní ìmọ̀ tí ó jinlẹ̀ nípa àṣà àti ohun àyíká wọn. 4. 5 Àlọ́ Àpagbè /Àlọ́ Onítàn Tàbí Àlọ́ Olórin Àlọ́ àpagbè dá lórí ìtàn tí ó kún fún ọgbọ́n akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ , kìí ṣe gbogbo àlọ́ onítàn ni ó máa ń ní orin, àwọn mìíràn ń sọ ìtàn ìdí abájọ, “ọ̀rọ̀ gbogbo kìí sé lórí Alábahun”, Ìjàṕa tìrókò ọkọ Yáníbo ni Yorùbá saábà máa ń fi ṣe olú ẹ̀dá ìtàn àlọ́ onítàn nítorí pé wọ́n gbà pé Alábahun (Ìjàpá) ni ó ní ọgbọ́n ẹ̀wẹ ́ jùlọ nínú ẹranko. Lára irúfẹ́ àwọn ìtàn tí ó sáábà máa ń jẹyọ ni ó bí Igún ṣe pá lórí, bi Ìjapá ṣe ṣàsejù tí ó tẹ ́ lọ́wọ́ àna rẹ̀ , bí Ìjàpá ṣe kó gbogbo ọgbọ́n ayé sínú akeǹgbè, Ìjàpá àti ìyá alákàrà, Ìjàpá, Kọ̀ lọ̀kọ̀ lọ̀ àti Adìẹ, Ìjàpá àti Àkùkọ, bí Ìjàpá àti Ajá ṣe lọ jí iṣu wà lóko olóko, Ìjàpá, àgbẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ , ìdí tí orí Ìjàpá fi pa, ìdí tí àṣà fi ń gbé ọmọ adiẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn ọ̀rẹyìn, àwọn ìtàn wọ̀nyí wà láti kọ́ ọmọdé lọ́gbọ́n kí wọ́n lè ní ìmọ̀ àti òye lórí ìrìnàjò ilé ayé ni. Àlọ́ àpagbè máa ń ní ìlànà lílé àti ègbè nínu orin rẹ̀ . Àpẹẹrẹ Ìṣíde Àlọ Àpagbè Apààlọ́ Àlọ́ oo Agbaàlọ̀ó Àlọ Apaàlọ́ Àlọ́ mí dá firigbágbòó, ó dá lórí ìjàpá tìrókò ọkọ Yáníbo ese daindain bí aran ọpẹ tó kọ́lé kọ́lé tó fi iran bàájẹ ́ . Tí ń lọ láàrín ẹ̀pà típàkọ́ rẹ̀ ń hàn firifiri. Ó ní ọpẹ ́ ́lọpẹ́ pé òun ga! Babalọlá (2018:1). Yoruba GNS Page 29 of 199 Ìsíde àlọ́ àpagbé sáàbà máa ń le pẹ̀ lú ìta agba wo ji ..., Àpọ́nlé àti oríkì Ìjàṕa èyí ni ti rẹ̀ ọ̀kan agbaloo tẹ́ ẹ fún ìtàn náà yóò jẹ́ èyí tí ó kọni lọ́gbọ́n lórí ìgbé ayé àti ìmọ̀ àyíká wa. 4.6 Ìtàn Ìwásẹ̀(Myth) Ìtàn ìwásẹ̀ ni ìtàn arebajo tí a gbé kalẹ̀ láti sọ ìdí abájọ ní ọ̀nà tí ohun tí à ń sọ ìtàn nípa rẹ̀ yóò fi ní ìtumọ̀ tí a kò leè yiiri wò, tí yóò sì mú ni lọ́kàn lórí èrò kan, nínú Ibrahim, B.F (2008) .... A larger construction that frees concepts and emotions usually narrative in nature, a story or a fusion of stories when these stories are known by a set of people as chronological and interpretative arrangements of actual events and are recollective, they are myths. Thomas ṣàlàyé ìtàn ìwásẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbékalẹ̀ tí ó fìdí èrò kan múlẹ̀ ni ọ̀rọ̀ arobajo pẹ̀ lú ìtàn àpilẹ̀kọ. Nígbà tí àwọn ènìyàn kan bá ti mọ àwọn ìtàn wọ̀nyí tí wọ́n sì gbàgbọ́ nínú wọn, wọn yóò ríwọn gẹ́gẹ́ bí ìdí abájọ nǹkan kan tàbí ìṣẹ̀ lẹ̀ kan. Pàtàkì ìtàn ìwásẹ̀ ni láti jẹ́ kí á mọ ìdí abájọ nǹkan tàbí ìtàn tí ó rọ̀ mọ́ ọ kí á lè ní òye nípa rẹ̀ . Bákan náà ni Okpewho (1992) rí ìtàn ìwásẹ̀ bíi: .... The quality of fancy which includes the creative or configurative power in the human mind in various degrees of intensity. Èyí tí ó túmọ̀ sí “Àgbékalẹ̀ àtinúdá tí ó ní àròjinlẹ̀ tí ó mú ènìyàn lọ́kàn nínú iri ọ̀nà tí kò ṣe yiiri wò.” Okpe sọ síwájú síi pé irúfẹ ́ ìtàn wọ̀nyí máa ń mú ènìyàn lọ́kàn, ó sì máa ń mú kí ìgbàgbọ́ dúró lórí èròńgbà kan. Ṣóyinká (1962) ní tirẹ̀ rí ìtàn ìwásẹ̀ gẹ́gẹ́ bí lááríjà wàláàyè ẹ̀dá, ó ní gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ni ó ń tiraka àti ṣe àṣeyọrí nínú ìlàkàkà wọn látàri arabajo tí a gbé kalẹ̀ fún àti làlùyọ ẹ̀dá nínú ohunkóhun tí ó bá dáwọ́ lé. Ìtàn ìwásẹ̀ máa ń dúró gẹǵẹ́ bí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ àti ojú àmúwáyé ẹ̀dá. Ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn ni pé Ọlọ́run fún ẹ̀dá ènìyàn lágbára lórí iye àyíká tí ó rẹwà, oúnjẹ àti àwọn ohun èlò lóríṣiríṣi àti pé ikú náà ni yóò jẹ́ òpin gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí. Èyí jásí pé ayé ń yí ni kò dúró sójúkan. Láti ìyè sí ikú àkúdàáyà, àtúnbí, ọ̀run rere, ọ̀run àpáàdì gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń ríwọn, oríṣiríṣi bí a ṣe rí wọn nínú àwọn ìtàn ìwásẹ̀ káàkiri. Àpẹẹrẹ Ìtàn Ìwásẹ̀ Yorùbá ni àwọn ìtàn ìwásẹ̀ ni àwọn ìtàn orísun Yorùbá tí à ń bá pàdé nínú ẹsẹ̀ ifá, àwọn ìtàn ìlú kọ̀ọ̀kan àti ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀ wá. Ìtàn àwọn orìṣà àti bí wọ́n ṣe wá sí ilé ayé láti ọ̀run. 4.7 Ìtàn Àwọn Akọni (Legends) Eléyìí ni ìtàn àwọn tí ó lààmìlaka ní àwùjọ, tí wọ́n ṣe àwọn nǹkan tí ó tayọ tí wọ́n sì kó ipa pàtàkì nínú ìdàgbàsókè àwùjọ wọn. Ènìyàn ni wọ́n nígbà ayé wọn, ìtàn wọn kìí ṣe arobajo bí ó ti ń wáyé nínú ìtàn ìwásẹ̀ (myth). Ìtàn wọn kìí sáábà mú ìrújú tàbí iyèméjì wa. Àwòkọ́ṣe nípa wọn máa ń jẹ ́ ìwúrí fún àwùjọ tí wọ́n ti kópa ribiribi, ìdí nìyí tí àwùjọ fi ń gbé wọn gẹ́gẹ́ bí akọni. A lè pín ìtàn akọni sí ọ̀nà méjì: Yoruba GNS Page 30 of 199 a) Akọni ajẹmọ́ ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ b) Akọni ajẹmọ́ ọ̀rọ̀ ìfẹ́ Àpẹẹrẹ ìtàn akọni ajẹmọ́ ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ni àwọn akọni tí ó kó ipa pàtàkì lákòókò ìdásílẹ̀ ìlú tàbí àwùjọ kan. Mọrẹ̀mi jẹ ́ọ̀kan lára àpẹẹrẹ akọni-lóbìnrin ní ilẹ̀ Yorùbá tí ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìdúnkokò mọ́ni àwọn ẹ̀yà Ugbo o fi ẹ̀ jẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ jẹ́ fún odò Ẹ̀sìnmìrìn tí ó bá leè tìí lẹ́yìn láti borí àwọn ọ̀ tá wọ̀nyí fún Ìfẹ ́ . Ìtàn akọni ajẹmọ́ ìfẹ́ ni yóò dálé ìfẹ ́ láàrín àwọn ènìyàn méjì láyé ìgbaànì, èyí tí ó yoo ní ọgbọ́n kan pàtó tí yóò kọ́ àwùjọ. Ó sì tún máa ń ní ṣe pẹ̀ lú ẹ̀ jẹ́ jíjẹ́ , ẹbọ rírú, àdéhùn ṣíṣe, oògùn ṣíṣe, owó dídá padà, ọfọ̀ ètùtù àti bẹẹ̀́ bẹ́ẹ̀ lọ. Àpẹẹrẹ irú èyí kan ni Ìtàn Ṣàngó àti Ọya. Díẹ̀ nínú àwọn akọni ilẹ̀ Yorùbá ni: Odùduwà Atẹ ̀wọ ̀nrọ ̀ , Ọ ̀ ránmíyàn Odede Akanatunkansi, Mọrèmi Ajásórò, Ògúnmọ ́ lá Olódòngboro Kẹ ̀rilógun, Ògèdèngbé Agbegungboro, Líṣàbi Agbòngbò Àkàlà, Ẹfúnróyè Tínuúbú, Ọbáfẹ ́mi Awólọ ́wọ ̀ , abbl. 4.7.1 Odùduwà Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé Odùduwà ní babańlá àwọn. Ìtàn kan sọ pé rírọ̀ ni ó rọ̀ láti ọ̀run sí Ilé- Ifẹ̀ . Ìtàn mìiŕaǹ sọ pé ìlú Mẹ́kà ni ó ti wá, òmíràn sì sọ pé ̀ apá Òkè-Ọya ní àríwá Nàìjíríà ni ó ti wá tí ó sì tẹ̀dó sí Ilé-Ifẹ̀ . Ibi yòówù tí Odùduwà ti wá, òdodo tí a dì mú ni pé òun ni ó jẹ Ọba àkọ́kọ́ ní Ilé-Ifẹ̀ . Ìgbàgbọ́ sì ni pé òun yìí kan náà ni ó ṣe àwọn ọba aládé ilẹ̀ Yorùbá sílẹ̀ . Ìtàn kan tilẹ̀ sọ pé ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọ̀kànbí, Ọ̀kànbí náà sì tún bímoọ méje mìíràn tí gbogbo wọ́n jẹ ́Ọba ní àwọn ìlú tí wọ́n padà tẹ̀dó sí. Àwọn Yorùbá ilẹ̀ Nàìjíríà àti àwọn ìĺú Yorùbá kan ní orílẹ̀ èdè Bìní. Wọ́n fi orúkọ Odùduwà sọ ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndírì kan ní Ilé-Ifẹ̀ . 4.7.2 Ọ̀ránmíyàn Ìtàn sọ pé ọ̀kan ninú àwọn ọmọ Odùduwà ni Ọ̀ránmíyàn. Òun yìí kan náà ló ń jẹ́ Odede. Ìtàn sọ pé jagun jagun ni, òun ló sì jagun gbalẹ̀ títí tí ó fi tẹ̀dọ́ sí Ọ̀yọ́ ilé. Ìwádìí fi yé wa pé Ọ̀ránmíyàn yìí kan náà ni wọ́n sọ pé wọ́n ń fi ọdún Olójò ṣe ìrántí rẹ̀ ní Ilé-Ifẹ̀ lọdọ́ọdún. Ìtàn tún sọ pé Ọ̀ránmíyàn ni Aláàfin àkọ́kọ́ , òun sì ni bàbá Ewédémi Arábánbi Àjàlá Ìjì tí wọ́n tún ń pè ní Ṣàngó. Owon kan wà ní Ilé-Ifẹ ́ tí wọ́n fi perí Ọ̀rànmíyàn, Ọ̀pá Ọ̀rànmíyàn ni wọ́n ń pè é, wọ́n fi orúkọ Ọ̀rànmíyàn sọ ilé ̀-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndírì kan. 4.7.3 Mọ́remí Ákikánjú obìnrin ni Mọrèmí, ìtàn sọ pè ìlú Ilé-Ifẹ̀ ló ti hùwà akọni. Ìtàn fi ýe wa pé ọmọ ìlú Ọ̀fà ní ìpínlẹ̀ Kúárà ni, ṣùgbọ́n ìlú Ilé-Ifẹ̀ ló ti hùwà akọni. Ìtàn fi yé wa pé Mọrèmi ló fi ara rẹ̀sílẹ̀ láti mọ àṣírí àwọn tí wọn díbọ́n ṣe bí ẹbọra tí wọ́n ń dààmú Ilé-Ifẹ̀ lásìkò ìjọba Oọ̀ni Aláyémore. Morèmí bá ogun àwọn Ígbò (àwọn ènì ̀yàn Ọbàtálá) lọ, ó sì di ayaba ọba àwọn Ígbò. Ọba tú àṣírí Yoruba GNS Page 31 of 199 àwọn ènìyàn rẹ̀ fún Mọrèmi. Mọrèmi sá padà sí Ilé-Ifẹ̀ ó si tú àṣírí àwọn Ígbò fún àwọn ènìyàn rẹ̀ . Àwọn Ígbò padà wọ̀ jà Ilé-Ifẹ̀ ní ogun, àwọn Ifẹ̀sì ṣẹ́gun wọn. Lẹ́yìn ogun ni Mọrèmi padà lọ dúpẹ ́ lọ́dọ̀ odò Ẹsìnmìnrìn tí ó sì mú ẹ̀bùn lọ fún un. Gbogbo ẹ̀bùn tí ó mú lọ fún ẹbora odò ló kó àyàfi Olúorógbó tí í ṣe ọmọ kan ṣoṣo tí Mọrèmi bí. Ó fi Olúorógbó káábọ̀ sí Ẹsìnmìnrìn torí pé odò náà ló ṣe àtìlẹyìn fún Mọrèmi tó fi lọ sí ogun Ígbò tí ó sì ja àjàṣẹ́gun. Àwọn Ifẹ̀ máa ń ṣe ọdún Èdì ní Ìrántí Mọrèmi tí ó fi ọmọ bíbí inú rẹ̀ kan ṣoṣo Olúorógbó rúbọ. Nítorí ìgbàlà, ìtúsílẹ̀ , ìṣẹ́gun àti àláfíà àwọn ènìyàn ìlú Ilé-Ifẹ̀ . Bákan náà ni wọ́n fi orúkọ Olúorógbó fúnra rẹ̀sọ ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndírì kan ní Ilé-Ifẹ̀ . 4.7.4 Baṣọ̀run Ògúnmọ́ lá Ọ̀kan pàtàkì nínú akọni ilẹ̀ Yorùbá ni Ògúnmọ́ lá. Jagun jagun Ìbàdàn ni Ògúnmọ́ lá. Ògúnmọ́ lá ni ó fi tẹ̀mítẹ̀mí ja ogun tí Ìjàyè àti Ìbàdàn jà láyé ìgbà tí Kúrunmí ṣaájú ogun Ìjàyè, Ògúnmọ́ lá ja àjàṣẹǵun. Aláàfin Adelu sì fi jẹ Baṣọ̀run. Baṣọ̀run Ògúnmọ́ lá jẹ́ olótìítọ́ àti olódodo, ó fi ẹsẹ̀ ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ kì í ṣègbè lẹ́yìn ẹnìkankan. Òun kì í gba àbẹ̀ tẹ́ lẹ̀ èyí ló sì fi kápá àwọn agbẹ̀yìnbẹbọjẹ ́ . Wọ́n máa ń ki Ògúnmọ́ lá ní Olódòdoogboro kẹ̀ri lóógun. 4.7.5 Lísàbi Akọni tí àwọn Ẹ̀gbá kò le è gbàgbé ni Lísàbi. Wọ́n tilẹ̀ gbà pé ọmọ Lísàbi ni àwọn. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé Lísàbi kọ́ ló tẹ Ẹg̀bá dó ṣùgbọ́n òun ló gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ìjẹgàba, ìmúnisìn, ìrẹ ́ jẹ àti ìyànjẹ àwọn ìlàrí Ọlọ́yọ̀ọ́ (Aláàfin Ọ̀yọ́) tí wọ́n jẹ ́Ajẹ ́ lẹ̀ ní ààrin àwọn Ẹg̀bá. Lísàbi ló dá ẹgbẹ ́àáró sílẹ̀ ní àárìn àwọn Ẹ̀gbá. Ẹgbẹ́ àáró ni ó padà di ẹgbẹ́Jagun jagun. Ẹgbẹ́ yìí ni àwọn Ẹ̀gbá fi jagun tí wọ́n sì di òmìnira kúrò lábẹ́ àjàgà Ọlọ́yọ̀ọ́ àti àwọn ìlàrí rẹ̀ . Àwọn Ẹ̀gbá máa ń ṣe ọdún Líṣàbi lọ́dọ́ọdún, wọ́n sì máa ń lọ si igbó Líṣàbi láti buyì fú ́n akọni tó ti lọ. Àwọn Ẹ̀gbá fi orúkọ Líṣàbi sọ ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndírì ní ìlú Abẹ́òkuta. 4.7.6 Tinúubú Obìnrin ni Tinúubú. Ẹfúnróyè ni orúkọ rẹ̀ mìíràn. Bí Tinúubú ṣe hùwà akọni ní ìlú Èkó bẹẹ̀́ náà ló ṣe ní Abẹ́òkuta. Tinúubú fi owó, ẹ̀bùn, ọta àti ẹ̀ tù ran Akíntóyè lọ́wọ́ nígbà tí ó ń du oyè Ọba Èkó. Ó ṣeni láàánú pé Dòsùmú ọmọ Ọba Akíntóyè náà ló padà lé Tinúubú kúrò ní Èkó. Ó sì padà sí Abẹò́kuta. Tinúubú ko ipa tó jọjú nínú ètò òṣèlú, òwò ṣíṣe àti ogun jíjà. Tinúubú fúnra rẹ̀ wọ aṣọ ogun ó sì mú ibùdó ogun sí Bodè Òwu lásìkò ìgbà tí àwọn Ẹ̀gbá àti Ọba Dàhọ̀mì ń bá ara wọn jagun. Tinúubú fi oúnjẹ àti nǹkan ìjà ogun ṣe àtìlẹyìn fún ogun Ẹ̀gbá. Ẹg̀bá sì ja àjàṣẹgun. Àwọn Ẹ̀gbá fi Tinúubú jẹ́Ìyálóde Ẹg̀bá. Àwọn ará Èkó sọ àdúgbò ńlá kan ní ìta Tinúubú. 4.7.7 Awólọ́wọ̀(1909-1987) Ọmọ Ìjẹ̀bú Ìkẹ́nnẹ́ ni Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ṣùgbọ́n káàkiri ilẹ̀ Nàìjíría ni òkìkí rẹ̀ kàn dé. Akọni òde-òní ni Awólọ́wọ̀ . Àgbà olóṣèlú ni, akíkanjú agbẹjọ́rò sì ni pẹ̀ lú. Òun ló dá ẹgbẹ ́ọmọ Yoruba GNS Page 32 of 199 odùduwà silẹ ́fún ìsọ̀kan àti ìtẹ̀síwájú àwọn ọmọ Yorùbá. Ẹgbẹ ́ọmọ Odùduwà ló padà di ẹgbẹ ́ olóṣèlú afẹ́nifẹŕe. (Action Group). Gẹ́gẹ ́bí olóòtù ìjọba ìpínlẹ̀ Ìwọ̀-oòrùn, Awólọ́wọ̀ darí ìjọba tí ó ṣètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ẹb́ẹ̀rẹ̀ ìpínlẹ̀ Ìwọ̀-oòrùn. Bákan náà ni ìjọba rẹ̀ dá ilé- iṣẹ́ tẹlifíṣàn àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní apá Ìwọ̀-oòrùn sílẹ̀ . Ìjọba náà mú ìgbéga bá iṣẹ́ àgbẹ̀ , ó ṣe ìdásílẹ̀ ilé- iṣẹ́ olókoòwò Oòdùà, ó dá ilé ẹ̀kọ́ gíga yunifásítì Ifẹ̀ sílẹ̀ , ó ṣe ìdásílẹ̀ àjọ tí ó ń ṣàkóso ìrìnàjò mímọ́ , àwọn Mùsùlùmí; ó sì kọ pápá ìṣiré Líbátì sí ìlú Ìbàdàn. Yàtọ̀ sí gbogbo àṣeyọrí wọ̀nyí, Awólọ́wọ̀ jà fitafita fún gbígba òmìnira fún ilẹ̀ Nàìjíríà. Ìjọba Ààrẹ Shehu Shagari fún un ní ọ̀kan nínú àwọn oyè ìdánilọ́ lá tó ga jùlọ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (GCFR). Ó kú ní ọdún 1987. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìlàkàkà rẹ̀ láti jẹ ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà ló já sí pàbo, àwọn èèyàn kan gbà pé atọ́ọ́atẹ ́ lẹ̀ ọkùnrin ni, àyànmọ́ ni kò jẹ ́kí ó dépò ààrẹ. Wọ́n fi orúkọ Awólọ́wọ̀ sọ ilé-ẹ̀ko gíga Yunifásítì Ifẹ̀ . 4.7.8 Ìkádìí A ti gbìyànjú sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí ohun tí àlọ́ jẹ́ , ìwúlò rẹ̀ , akitiyan àwọn ọ̀ jọ̀gbọ́n àsìkò tí à ń pa àlọ́ , a sì ti ṣíṣọ lójú eégún ìtàn ìwásẹ̀ , ìtàn àwọn akọni ní ilẹ̀ Yorùbá. Èrò ti wa ni pé tí a bá lè tẹra mọ́ ṣíṣe ẹ̀dà àlọ́ tún, tí a sì ń mú wọn lò lóòrèkóòrè nínú gẹ́gẹ ́bí ọ̀nà tí a fi ń gbé àṣà wa lárugẹ. Tí a sì tún jẹ́ àwọn èwe ìwòyí ní òye àwọn ìtàn ìwásẹ̀ àti ti àwọn akọni wa, ó dájú pé gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kò ní rọkún ìgbàgbé, wọn kò ní kú àkúrun áṣà wa yóò sì lè fagagbága pẹ̀ lú àwọn àṣà mìíràn tí à ń nàgà wò lágbàáyé. 4.8 Orin Àti Ewì Kéékèèké 4.8.0 Ìfáàrà Àwùjọ sòṛò́ṣ ́òṛò́ ̣́ àti kọrin-kọrin ní àwùjọ Yorùbá. Kò sí àwùjọ tí wọn kìí ti í kọrin láyé, bí èḍ́ á ènìyàn ti ń kọrin, béẹ ́ ̀ ̣́náà ni àwọn ẹranko, ẹyẹ, kòkòrò, kódà àwọn ohun aláìléṃ́ ìí gan an bíi aféf̣é́ , od ̣́ ò, òkè, ewéko àti béẹ́ ̀ ̣́béẹ ́ ̀ ̣́lọ ń kọrin. Ò ̣́kan lára èỵ ́à lítíréṣò ̣́alohùn tí èḍ́ á ènìyàn ń lò ni òṇ́ à àrà láti fi gbé èrò ọkàn rè ̣́jáde pè ḷú́ ìmòṣ ́ílara tí yóò mú olùgbó ̣́lóḳ ́àn ṣinṣin ni orin jé .̣ ́ 4.8.1 Oríkì Orin Orin niàkójọpò ̣́ohùn dídùn tí a fi dára, tí ó kún fún ẹwà ìpèdè tí ó ní ìgbésè ̣́dogbandogba pè ḷú́ àjọṣepò ̣́tó mú adùn jáde. Orin ní ohùn tí a fi ń gbé e jáde, èyí tí ó yàtò ̣́sí ti òṛò́ ̣́geere tàbí èdè ojoojúmó .Ḳ́ ò sí ìgbà tí Yorùbá kò le kọrin; ó lè jé ̣́lénu i ̣́ ṣé , l ̣́ énu ̣́ ìsinmi, lákòókò ayò , l ̣́ ákòókò ìbànújé , l ̣́ ákòókò ayẹyẹ lóríṣìíríṣìí. Gbogbo nǹkan ni Yorùbá ní orin fún. Bí orin ọmọdé ṣe wà, béẹ ́ ̀ ̣́ni orin ìrẹmọléḳ ́ùn wà, orin ìdárayá náà kò gbéỵ ́ìn. Àpẹẹrẹ àwọn orin wònỵ ́ìí ni: Orin ìrẹmọlé ḳ ́ún: Orin ìkìlo ̣́fún ọmọdé: (1) Lákúrùbútutu ọmọ wá jó o (1) Òjò ń rò ̣́ Ọmọ ló yẹni Ṣeré nínú ilé Má wọnú òjò (2) Ó tó ọmọ mi o, ó tó Kí aṣọ rẹ má ba à tutù Ṣebí mo ti rè ̣́ó ̣́léẹ ́ ̀kan ̣ ́ Yoruba GNS Page 33 of 199 O láṣejú lóẉ́ ó ̣́o. (2) È ̣́yin ọmọdé ẹ má sàfojúdi o (3) Àkàndé o Àfojúdi o, ló ń je ̣́ ̀nìyàn níyà o. Kò roko abbl. Àkàndé o Kò rodò Bó bá jí A gbóḅ ́è ̣́kaná Jèḅ́ à tán A ṣekùn rondo Ọmọ ọlóṛò́ ̣́tí í jẹyin awó Orin èébú: Orin amúṣé ỵá́: (1) Ìyálé mi bà mí jé ̣́ (1) Tèmí kò ní ṣòróo ṣe Ó ní mo gbérú Lóḍ́ ò ̣́rẹ baba Ìyálé mi bà mí jé ̣́ Tèmi kò ní ṣòróo ṣe Ó ní mo gbéyò ̣́ Lóḍ́ ò ̣́rẹ baba Kí ni n ó fi bàyálé jé?̣ ́ Eléyín ọkọ́ ́ (2) Ìwé kíkọ́ ́ Kí ni n ó fi bàyálé jé?̣́ Láì sí ọkó ̣́àti àdá Elétè ajò ̣́o Kòì pé o Ìyálé mi dètè bò mí Kòì pé o Otútù yìí pòọ́ ̀ọ́ ̀ ̣́ Iṣé ̣́àgbè ̣́ni iṣé ̣́ilè ̣́wa Ẹni kò ṣiṣé ̣́ (2) Ó ṣe bí mo féẹ ́ ́ ̣́kọkọ mi Yóò mà jalè Kò lè rí yàrá mi lò Ìwé kíkó ̣́ Ó ṣe bí... Láì sí ọkó ̣́àti àdá Ó ṣe bí mo féẹ ́ ́ ̣́kọkọ ni o, Kòì pé o Kò lè rí yàrá mi lò Kòì pé o o o. Kó rí ó pé Orin ìdárayá: Lílé: Ẹkùn méraṇ́ Ègbè: Mè ̣́é ̣́è!̣ ́ Lílé: Ẹkùn méraṇ́ Ègbè: Mè ̣́é ̣́è!̣ ́ Lílé: Ó korí bọgbó Ègbè: Mè ̣́é ̣́è ̣́ Lílé: Ó kọrùn bọsà Ègbè: Mè ̣́é ̣́è!̣ ́ Lílé: Ojú ẹkùn póṇ́ Ègbè: Ìrù ẹkùn le Yóó mú o! Kòì mu o! 4.8.1.1 Ìpínsísòṛí́ Orin 4.8.1.1.1 Orin Ajẹmó ̣́Ẹ́̀ka-Èdè Àwọn orin Ajẹmọ èkạ́ -èdè Yorùbá ni àwọn orin ìbílè ̣́tí ó jé ̣́pé èkạ ́-èdè Yorùbá ni a mò ̣́wón ṃ́ ó . ̣́ Àwọn orin Yorùbá Ajẹmọ́ ́ èkạ ́-èdè máa ń sàn láti ìpínlè ̣́kan dé òmíràn. Ẹ je ̣ ́ ́ ká wo díè ̣́lára àwọn orin Ajẹmọ́ ́ èkạ ́-èdè: • Ẹkún Ìyàwótí wón ṃ́ áa ń sun ní Ò ̣́yó , ̣́ Ìbàdàn, Ìgbómìnà, Ìpínlè ̣́Ò ̣́yó ̣́àti Ìpínlè ̣́Ò ̣́ṣun. Àsìkò ìgbà tí ọlóṃ́ ọge bá ń lọ sí ilé ọkọ ni wón ṃ́ áa ń sun ẹkún ìyàwó, àwọn ọmọbìnrin ló sì máa ń sun ẹkún ìyàwó. • Dadakúàdàtí wón ṃ́ áa ń sun ni ìlú Ìlọrin ní ìpínlè ̣́Kwara. Àwọn ọkùnrin ló ń kọ ó .̣ ́